Tí mo bá gbọdò kú
Translated to Yoruba by @ayoTweetzTí mo bá gbọdò kú
Ìwọ kò gbódò kú
Kí o lè sọ ìtàn mí
Kí o lè ta gbogbo ohun iní mí
Kí o lè bàa ra aso funfun kan àti okun
Tí yóò máa jẹ àmì
Fún ọmọdé Gaza kan
Tí ó ń wo sánmà pèlú ìrètí pé Baba òun ń bộ
Lai mọ wípé ó ti di ẹni àn á
Ó ti lọ lái dágbére
Kò dágbére fún ẹbí tàbí ará
Kò tilè lè dágbére fún ara rè
Tí ọmọdé náà bá rí aso funfun náà tó ń fò lókè lókè
Kí ó lè máa ronú pé Malaika kan ń bộ láti òkè
pèlú ìfé
Tí mo bá gbọdò kú
Jẹ kí ikú mí mú ìrètí wá
Jẹ kí ó di ìtàn